1 Kọrinti 10:19
1 Corinthians 10:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan?
1 Corinthians 10:19 in English
1 Corinthians 10:19 · Berean Standard Bible
Am I suggesting, then, that food sacrificed to an idol is anything, or that an idol is anything?
Context
17Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo. 18Ẹ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí? 19Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan? 20Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù. 21Ẹ̀yin kò lè mu nínú ago tí Olúwa àti ago ti èṣù lẹ́ẹ̀kan náà; ẹ̀yin kò le ṣe àjọpín ní tábìlì Olúwa, àti ni tábìlì ẹ̀mí èṣù lẹ́ẹ̀kan náà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.