1 Kọrinti 10:18
1 Corinthians 10:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí?
1 Corinthians 10:18 in English
1 Corinthians 10:18 · Berean Standard Bible
Consider the people of Israel: Are not those who eat the sacrifices fellow partakers in the altar?
Context
16Ǹjẹ́ ago ìdúpẹ́ nípasẹ̀ èyí tí a ń dúpẹ́ fún, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín ìdàpọ̀ nínú ẹ̀jẹ̀ Kristi bí? Àkàrà tí a bù, kì í ha ṣe jíjẹ́ alábápín nínú ara Kristi bi? 17Nítorí àkàrà kan ni ó ń bẹ, àwa tí a pọ̀ níye, tí a sì jẹ ara kan ń pín nínú àkàrà kan ṣoṣo. 18Ẹ wo Israẹli nípa ti ara, àwọn tí ń jẹ ohun ẹbọ kò ha ṣe alábápín pẹpẹ bí? 19Ǹjẹ́ kí ni mo ń wí? Ṣé pé ohun tí a fi rú ẹbọ sí òrìṣà jẹ́ nǹkan kan tàbí pé òrìṣà jẹ́ nǹkan kan? 20Rárá, ṣùgbọ́n ohun tí mo ń wí ni pé, ohun tí àwọn aláìkọlà fi ń rú ẹbọ wọn fi fun àwọn ẹ̀mí èṣù. Dájúdájú kì í ṣe ìrúbọ sí Ọlọ́run. Èmi kò sì fẹ́ kí ẹnikẹ́ni nínú yín so ara rẹ̀ pọ̀ mọ́ ẹ̀mí èṣù.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.