1 Kronika 29:20
1 Chronicles 29:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, “Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín.” Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba.
1 Chronicles 29:20 in English
1 Chronicles 29:20 · Berean Standard Bible
Then David said to the whole assembly, “Blessed be the LORD your God.” So the whole assembly blessed the LORD, the God of their fathers. They bowed down and paid homage to the LORD and to the king.
Context
18Olúwa Ọlọ́run àwọn baba a wa Abrahamu, Isaaki àti Israẹli pa ìfẹ́ yìí mọ́ nínú ọkàn àwọn ènìyàn rẹ títí láé pẹ̀lú pípa ọkàn mọ́ lóòtítọ́ sí ọ. 19Àti fún ọmọ mi Solomoni ní ìfọkànsìn tòótọ́ láti pa àṣẹ rẹ mọ́ àwọn ohun tí ó nílò àti òfin àti láti ṣe ohun gbogbo láti kọ́ ààfin bí ti ọba fún èyí tí mo ti pèsè.” 20Dafidi sì sọ fún gbogbo ìjọ ènìyàn pé, “Nísinsin yìí, ẹ fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run yín.” Gbogbo ènìyàn sì fi ìyìn fún Olúwa Ọlọ́run àwọn baba wọn, wọ́n sì tẹ orí wọn ba, wọ́n wólẹ̀ fún Olúwa àti ọba. 21Ni ọjọ́ kejì, wọ́n rú ẹbọ sí Olúwa, wọ́n sì rú ẹbọ sísun sí i: ẹgbẹ̀rún (1,000) kan akọ màlúù, ẹgbẹ̀rin (1,000) kan àgbò, àti ẹgbẹ̀rin kan akọ ọ̀dọ́-àgùntàn. Lápapọ̀ pẹ̀lú ọrẹ mímu àti àwọn ẹbọ mìíràn ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ fún gbogbo Israẹli. 22Wọ́n jẹ wọ́n sì mu pẹ̀lú ayọ̀ kíkún ní iwájú Olúwa ní ọjọ́ náà.
Nígbà náà wọ́n yan Solomoni ọmọ Dafidi gẹ́gẹ́ bí ọba lẹ́ẹ̀kejì wọ́n fi àmì òróró yàn án níwájú Olúwa láti ṣe olórí àti Sadoku láti ṣe àlùfáà.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.