1 Kronika 27:26
1 Chronicles 27:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà.
1 Chronicles 27:26 in English
1 Chronicles 27:26 · Berean Standard Bible
Ezri son of Chelub was in charge of the workers in the fields who tilled the soil.
Context
24Joabu ọmọ Seruiah bẹ̀rẹ̀ sí ní kà wọ́n, ṣùgbọ́n kò parí kíkà wọ́n nítorí, ìbínú dé sórí àwọn Israẹli nípasẹ̀ kíka iye àti iye náà, a kò kọ ọ́ sínú ìwé ìtàn ayé ti ọba Dafidi. 25Asmafeti ọmọ Adieli wà ní ìdí ilé ìṣúra ti ọba.
Jonatani ọmọ Ussiah wà ní ìdí ilé ìṣúra ní iwájú agbègbè nínú àwọn ìlú, àwọn ìletò àti àwọn ilé ìṣọ́. 26Esri ọmọ Kelubu wà ní ìdí àwọn òṣìṣẹ́ lórí pápá, tí wọ́n ń ko ilẹ̀ náà. 27Ṣimei ará Ramoti wà ní ìdí àwọn ọgbà àjàrà.
Sabdi ará Sifmi wà ní ìdí mímú jáde ti èso àjàrà fún ọpọ́n ńlá tí a ń fi ọ̀tún èso àjàrà sí. 28Baali-Hanani ará Gederi wà ní ìdí olifi àti àwọn igi sikamore ní apá ìhà ìwọ̀-oòrùn àwọn ní ẹ̀ṣẹ̀ pẹ̀tẹ́lẹ̀.
Joaṣi wà ní ìdí fífún ni ní òróró olifi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.