Native Bible

1 Chronicles 26:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀.

1 Chronicles 26:18 in English

1 Chronicles 26:18 · Berean Standard Bible

As for the court * on the west, there were four at the highway and two at the court.

Context

16Kèké fún ẹnu-ọ̀nà ìhà ìwọ̀-oòrùn àti Ṣaleketi ẹnu-ọ̀nà ní ọ̀nà apá òkè bọ́ sí ọ̀dọ̀ Ṣuppimu àti Hosa. Olùṣọ́ wà ní ẹ̀bá olùṣọ́. 17Àwọn ará Lefi mẹ́fà ní ó wà ní ọjọ́ kan ní ìhà ìlà-oòrùn, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà àríwá, mẹ́rin ní ọjọ́ kan ní ìhà gúúsù àti méjì ní ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo ní ilé ìṣúra. 18Ní ti ilé ẹjọ́ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn, mẹ́rin sì wà ní ojú ọ̀nà àti méjì ní ilé ẹjọ́ fúnra rẹ̀. 19Wọ̀nyí ni ìpín ti àwọn olùtọ́jú ẹnu-ọ̀nà tí wọ́n jẹ́ àwọn ìran ọmọ Kora àti Merari. 20Láti inú àwọn ọmọ Lefi, Ahijah ni ó wà lórí ìṣúra ti ilé Ọlọ́run àti lórí ìṣúra nǹkan wọ̀n-ọn-nì tí a yà sí mímọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.