Native Bible

1 Chronicles 24:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

1 Chronicles 24:2 in English

1 Chronicles 24:2 · Berean Standard Bible

But Nadab and Abihu died before their father did, and they had no sons; so Eleazar and Ithamar served as priests.

Context

1Àwọn wọ̀nyí sì ni pínpín àwọn ọmọ Aaroni. Àwọn ọmọ Aaroni ni Nadabu, Abihu, Eleasari àti Itamari. 2Ṣùgbọ́n Nadabu àti Abihu kú kí ó tó di wí pé baba wọn kú, wọn kò sì ní àwọn ọmọ; bẹ́ẹ̀ ni Eleasari àti Itamari sì ṣe gẹ́gẹ́ bí àlùfáà. 3Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Sadoku ọmọ Eleasari àti Ahimeleki ọmọ Itamari, Dafidi sì yà wọ́n nípa nínú ìpín fún ìyàsọ́tọ̀ àwọn iṣẹ́ ìsìn wọn. 4A rí ọ̀pọ̀ àwọn olórí lára àwọn ọmọ Eleasari ju lára àwọn ọmọ Itamari lọ, wọ́n sì pín wọn lẹ́sẹ lẹ́sẹ: mẹ́rìndínlógún olórí láti ìdílé ọmọ Eleasari ìran wọn àti olórí méjọ ìdílé láti ara àwọn ọmọ Itamari.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.