1 Kronika 23:2
1 Chronicles 23:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi.
1 Chronicles 23:2 in English
1 Chronicles 23:2 · Berean Standard Bible
Then he gathered all the leaders of Israel, as well as the priests and Levites.
Context
1Nígbà tí Dafidi sì dàgbà, tí ó sì di arúgbó, ó sì fi Solomoni ọmọ rẹ̀ jẹ ọba lórí Israẹli. 2Ó sì kó gbogbo àgbàgbà Israẹli jọ, àti gẹ́gẹ́ bí àwọn àlùfáà àti àwọn ará Lefi. 3Àwọn ọmọ Lefi láti ọgbọ̀n ọdún tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ni wọ́n kà àpapọ̀ iye àwọn ọkùnrin wọn sì jẹ́ ẹgbàá mọ́kàndínlógún (38,000). 4Dafidi sì wí pe, ní ti èyí, ẹgbàá méjìlá (24,000) ni kí wọn jẹ́ alábojútó iṣẹ́ ilé fún Olúwa àti ẹgbẹ̀rún mẹ́fà (6,000) ni kí ó ṣe olórí àti onídàájọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.