1 Kronika 22:12
1 Chronicles 22:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́.
1 Chronicles 22:12 in English
1 Chronicles 22:12 · Berean Standard Bible
Above all, may the LORD give you insight and understanding when He puts you in command over Israel, so that you may keep the Law of the LORD your God.
Context
10Òun ni ẹni náà tí yóò kọ́ ilé fún orúkọ mi. Yóò sì jẹ́ ọmọ mi, èmi yóò sì jẹ́ baba rẹ̀ èmi yóò sì fi ìdí ìtẹ́ ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ lórí Israẹli láéláé.’ 11“Nísinsin yìí, ọmọ mi, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ, kí ìwọ kí ó sì ní àṣeyọrí kí o sì kọ́ ilé Olúwa Ọlọ́run rẹ, àti gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ nípa rẹ. 12Kí Olúwa kí ó fún ọ ni ọgbọ́n àti òye nígbà tí ó bá fi ọ́ ṣe aláṣẹ lórí Israẹli, bẹ́ẹ̀ ni kí ìwọ kí ó lè pa òfin Olúwa Ọlọ́run mọ́. 13Nígbà náà ìwọ yóò sì ní àṣeyọrí tí ìwọ bá ṣe àkíyèsí láti mú àṣẹ àti ìdájọ́ àti òfin ti Olúwa ti fi fún Mose fun Israẹli ṣe. Bẹ́ẹ̀ ni ki ìwọ jẹ́ alágbára àti onígboyà. Má ṣè bẹ̀rù tàbí kí àyà má sì ṣe fò ọ́. 14“Èmi ti gba ìpọ́njú ńlá láti ṣe fún ilé Olúwa ọ̀kẹ́ márùn-ún tálẹ́ǹtì wúrà, àti ẹgbẹ̀rún ẹgbẹ̀rún tálẹ́ǹtì fàdákà, ìwọ̀n idẹ àti irin tí ó tóbi àìní ìwọ̀n, àti ìtì igi àti òkúta. Ìwọ sì tún le fi kún wọn.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.