1 Kronika 21:25
1 Chronicles 21:25 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà.
1 Chronicles 21:25 in English
1 Chronicles 21:25 · Berean Standard Bible
So David paid Ornan six hundred shekels of gold * for the site.
Context
23Arauna sì wí fún Dafidi pé, “Mú un fún ara rẹ, sì jẹ́ kí olúwa mi ọba kí ó ṣe ohun tí ó dára lójú rẹ̀. Wò ó, èmí yóò fún ọ ní àwọn màlúù fún ẹbọ sísun, àti ohun èlò ìpakà fún igi, àti ọkà fún ọrẹ oúnjẹ. Èmi yóò fun ọ ní gbogbo èyí.” 24Ṣùgbọ́n ọba Dafidi dá Arauna lóhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ kọ́, ṣùgbọ́n èmi yóò rà á ní iye owó rẹ̀ ní pípé, nítorí èmi kì yóò èyí tí ó jẹ́ tìrẹ fún Olúwa, tàbí láti rú ẹbọ sísun tí kò ná mi ní ohun kan.” 25Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi san ẹgbẹ̀ta (600) ṣékélì wúrà fún Arauna nípa ìwọ̀n fún ibẹ̀ náà. 26Dafidi sì tẹ́ pẹpẹ fún Olúwa níbẹ̀ ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ọpẹ́. Ó sì ké pe Olúwa, Olúwa sì fi iná dá a lóhùn láti òkè ọ̀run wá lórí pẹpẹ fún ẹbọ ọrẹ sísun. 27Nígbà náà Olúwa sọ̀rọ̀ sí angẹli, ó sì gbé idà padà bọ̀ sínú àkọ̀ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.