1 Kronika 21:1
1 Chronicles 21:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli.
1 Chronicles 21:1 in English
1 Chronicles 21:1 · Berean Standard Bible
Then Satan * rose up against Israel and incited David to take a census of Israel.
Context
1Satani sì dúró ti Israẹli, ó sì ti Dafidi láti ka iye Israẹli. 2Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì wí fún Joabu àti àwọn olórí àwọn ènìyàn pé, “Lọ kí o ka iye àwọn ọmọ Israẹli láti Beerṣeba títí dé Dani. Kí o sì padà mú iye wọn fún mi wa, kí èmi kí ó le mọ iye tí wọ́n jẹ́.” 3Ṣùgbọ́n Joabu dá a lóhùn pé, “Kí Olúwa kí ó mú àwọn ènìyàn rẹ̀ pọ̀ sí ní ìgbà ọgọ́rùn-ún ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, ọba olúwa mi, gbogbo wọn kì í ha ṣe ìránṣẹ́ olúwa ni? Kí ni ó dé tí olúwa mi ṣe fẹ́ ṣè yìí? Kí ni ó de tí yóò fi mú ẹ̀bi wá sórí Israẹli?”
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.