1 Kronika 20:1
1 Chronicles 20:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Joabu ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ammoni ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rabba. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dafidi dúró sí Jerusalẹmu Joabu kọlu Rabba, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun.
1 Chronicles 20:1 in English
1 Chronicles 20:1 · Berean Standard Bible
In the spring,* at the time when kings march out to war, Joab led out the army and ravaged the land of the Ammonites. He came to Rabbah and besieged it, but David remained in Jerusalem. And Joab attacked Rabbah and demolished it.
Context
1Ní àkókò àkọ́rọ̀ òjò, ni ìgbà tí àwọn ọba lọ sí ogun, Joabu ṣamọ̀nà àwọn ọ̀wọ́ ọmọ-ogun. Ó fi ilẹ̀ àwọn ará Ammoni ṣòfò. Ó lọ sí ọ̀dọ̀ Rabba. Ó sì fi ogun dúró tì í. Ṣùgbọ́n Dafidi dúró sí Jerusalẹmu Joabu kọlu Rabba, ó sì fi sílẹ̀ ní ìparun. 2Dafidi mú adé kúrò lórí àwọn ọba wọn ìwọ̀n rẹ̀ dàbí i tálẹ́ǹtì wúrà, a sì tò ó jọ pẹ̀lú àwọn òkúta iyebíye. A sì gbé e ka orí Dafidi. Ó kó ọ̀pọ̀ ìkógun láti ìlú ńlá náà. 3Ó sì kó gbogbo àwọn ènìyàn tí ó wà ní ibẹ̀ jáde, ó sì fi iṣẹ́ lé wọn lọ́wọ́ láti ṣiṣẹ́ pẹ̀lú ayùn àti ìtulẹ̀ onírin àti àáké. Dafidi ṣe eléyìí sí gbogbo àwọn ará ìlú Ammoni. Nígbà náà, Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ-ogun rẹ̀ padà sí Jerusalẹmu.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.