Native Bible

1 Chronicles 19:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́.

1 Chronicles 19:12 in English

1 Chronicles 19:12 · Berean Standard Bible

“If the Arameans are too strong for me,” said Joab, “then you will come to my rescue. And if the Ammonites are too strong for you, then I will come to your rescue.

Context

10Joabu ri wí pé àwọn ìlà ogun wà níwájú àti ẹ̀yìn òun, bẹ́ẹ̀ ni o mu àwọn ọmọ-ogun tí ó dára ní Israẹli, o sì tẹ́ ogun wọn sí àwọn ará Siria. 11Ó fi ìyókù àwọn ọkùnrin náà sí abẹ́ àkóso Abiṣai arákùnrin rẹ̀, a sì tẹ́ wọn kí wọn dojúkọ àwọn ará Ammoni. 12Joabu wí pé tí àwọn ará Siria bá le jù fún mi, nígbà náà, ìwọ ni kí o gbà mí; ṣùgbọ́n tí àwọn ará Ammoni bá le jù fún ọ, nígbà náà èmi yóò gbà ọ́. 13Jẹ́ alágbára kí ẹ sì jẹ́ kí a jà pẹ̀lú ìgboyà fún àwọn ènìyàn wa àti àwọn ìlú ńlá ti Ọlọ́run wa. Olúwa yóò ṣe ohun tí ó dára ní ojú rẹ̀. 14Nígbà náà Joabu àti àwọn ọmọ-ogun pẹ̀lú rẹ̀ lọ síwájú láti lọ jà pẹ̀lú àwọn ará Siria. Wọ́n sì sálọ kúrò níwájú rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.