1 Kronika 18:9
1 Chronicles 18:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba.
1 Chronicles 18:9 in English
1 Chronicles 18:9 · Berean Standard Bible
When King Tou * of Hamath heard that David had defeated the entire army of Hadadezer king of Zobah,
Context
7Dafidi mú àpáta wúrà tí àwọn ìjòyè Hadadeseri gbé, ó sì gbé wọn wá sí Jerusalẹmu. 8Láti Tibhati àti Kuni, àwọn ìlú Hadadeseri, Dafidi kó ọ̀pọ̀lọpọ̀ idẹ tí Solomoni lò láti fi ṣe okùn idẹ, àwọn òpó àti oríṣìí ohun èlò idẹ. 9Nígbà tí Tou ọba Hamati gbọ́ pé Dafidi ti borí gbogbo ọmọ-ogun Hadadeseri ọba Soba. 10Ó rán ọmọ rẹ̀ Hadoramu sí ọba Dafidi láti kí i àti láti lọ bá a yọ̀ lórí ìṣẹ́gun rẹ̀ nínú ogun lórí Hadadeseri, tí ó wà lójú ogun pẹ̀lú Tou. Hadoramu mú oríṣìíríṣìí ohun èlò ti wúrà àti fàdákà àti idẹ wá. 11Ọba Dafidi ya ohun èlò wọ́n yí sí mímọ́ fún Olúwa, gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe pẹ̀lú fàdákà àti wúrà tí ó ti mú láti gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè wọ̀nyí: Edomu àti Moabu, ará Ammoni àti àwọn ará Filistini àti Amaleki.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.