Native Bible

1 Chronicles 18:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá.

1 Chronicles 18:2 in English

1 Chronicles 18:2 · Berean Standard Bible

David also defeated the Moabites, and they became subject to David and brought him tribute.

Context

1Ní àkókò kan, Dafidi kọlu àwọn ará Filistini, ó sì ṣẹ́gun wọn. Ó sì mú Gati àti àwọn ìletò agbègbè rẹ̀ kúrò lábẹ́ ìdarí àwọn ará Filistini. 2Dafidi borí àwọn ará Moabu, wọ́n sì di ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀, wọ́n sì mú owó òde wá. 3Síbẹ̀, Dafidi sì kọlu Hadadeseri ọba Soba ní Hamati, bí ó ti ń lọ láti fi ìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀ létí odò Eufurate. 4Dafidi fi agbára gba ẹgbẹ̀rún (1,000) kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ẹ̀ẹ́dẹ́gbàárin (7,000) agun-kẹ̀kẹ́ àti ogún ẹgbẹ̀rún (20,000) ológun ilẹ̀. Ó sì já gbogbo ọgọ́rùn-ún iṣan ẹsẹ̀ àwọn kẹ̀kẹ́-ẹṣin náà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.