1 Kronika 16:31
1 Chronicles 16:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn; lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!”
1 Chronicles 16:31 in English
1 Chronicles 16:31 · Berean Standard Bible
Let the heavens be glad, and the earth rejoice. Let them say among the nations, ‘The LORD reigns!’
Context
29Fún Olúwa ní ìyìn nítorí orúkọ rẹ̀;
gbé ọrẹ kí ẹ sì wá síwájú rẹ̀.
Sìn Olúwa nínú inú dídùn ìwà mímọ́ rẹ̀. 30Wárìrì níwájú rẹ̀, gbogbo ayé!
Ayé sì fi ìdí múlẹ̀; a kò sì le è ṣí i. 31Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, jẹ́ kí ayé kí ó ṣe inú dídùn;
lẹ́ kí wọn kí ó sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, pé “Olúwa jẹ ọba!” 32Jẹ́ kí ọ̀run kí ó tún dún padà, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀;
Jẹ́ kí àwọn pápá kí ó hó fún ayọ̀, àti gbogbo ohun tí ó wà nínú rẹ̀! 33Nígbà náà ni igi igbó yóò kọrin,
wọn yóò kọrin fún ayọ̀ níwájú Olúwa,
nítorí tí ó wá láti ṣèdájọ́ ayé.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.