Native Bible

1 Chronicles 15:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un.

1 Chronicles 15:1 in English

1 Chronicles 15:1 · Berean Standard Bible

David constructed buildings for himself in the City of David, and he prepared a place for the ark of God and pitched a tent for it.

Context

1Lẹ́yìn ìgbà tí Dafidi ti kọ́ ilé fún ara rẹ̀ ní ìlú Dafidi. Ó sì fi ààyè sílẹ̀ fún àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run ó sì pàgọ́ fún un. 2Nígbà náà Dafidi wí pé, kò sí ẹnìkan àyàfi àwọn ọmọ Lefi ni ó lè gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run, nítorí Olúwa yàn wọ́n láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa àti láti máa ṣe ìránṣẹ́ níwájú rẹ̀ títí láé. 3Dafidi kó gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jọ ní Jerusalẹmu láti gbé àpótí ẹ̀rí Olúwa wá sí ibi tí ó ti pèsè sílẹ̀ fún un.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.