1 Kronika 13:10
1 Chronicles 13:10 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run.
1 Chronicles 13:10 in English
1 Chronicles 13:10 · Berean Standard Bible
And the anger of the LORD burned against Uzzah, and He struck him down because he had put his hand on the ark. So he died there before God.
Context
8Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli ni wọ́n ṣe àjọyọ̀ pẹ̀lú gbogbo agbára wọn níwájú Ọlọ́run, pẹ̀lú orin àti pẹ̀lú dùùrù, ohun èlò orin olókùn, tambori, kimbali pẹ̀lú ìpè. 9Nígbà tí wọ́n dé sí ilẹ̀ ìpakà Kidoni, Ussa sì na ọwọ́ rẹ̀ síta láti di àpótí ẹ̀rí Olúwa mú, nítorí màlúù kọsẹ̀. 10Ìbínú Olúwa, sì ru sí Ussa, ó sì lù ú bolẹ̀ nítorí o ti fi ọwọ́ rẹ̀ lórí àpótí ẹ̀rí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì kú síbẹ̀ níwájú Ọlọ́run. 11Nígbà náà Dafidi sì bínú nítorí ìbínú Olúwa ké jáde lórí Ussa, àti títí di òní, wọ́n sì ń pe ibẹ̀ ní Peresi-Usa. 12Dafidi sì bẹ̀rù Ọlọ́run ní ọjọ́ náà, ó sì béèrè pé, báwo ni èmi náà ó ṣe gbé àpótí ẹ̀rí Ọlọ́run sí ọ̀dọ̀ mi?
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.