Native Bible

1 Chronicles 11:3 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli.

1 Chronicles 11:3 in English

1 Chronicles 11:3 · Berean Standard Bible

So all the elders of Israel came to the king at Hebron, where David made a covenant with them before the LORD. And they anointed him king over Israel, according to the word of the LORD through Samuel.

Context

1Gbogbo àwọn Israẹli kó ara wọn jọ pọ̀ sí ọ̀dọ̀ Dafidi ní Hebroni, wọ́n sì wí pé, “Ẹran-ara rẹ àti ẹ̀jẹ̀ rẹ ni àwa í ṣe. 2Ní àtijọ́, kódà nígbà tí Saulu jẹ ọba, ìwọ ni ẹni tí ó darí Israẹli ní ojú ogun wọn. Olúwa Ọlọ́run rẹ sì wí fún ọ pé, ‘Ìwọ yóò sì jẹ́ olùṣọ́ Israẹli ènìyàn mi, ìwọ yóò sì jẹ́ olórí fún wọn.’ ” 3Nígbà tí gbogbo àwọn ìjòyè Israẹli tí wọ́n ti wá sọ́dọ̀ ọba Dafidi ni Hebroni. Ó sì ṣe májẹ̀mú pẹ̀lú wọn ní Hebroni níwájú Olúwa, wọ́n sì fi òróró yan Dafidi ní ọba lórí Israẹli, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa láti ọwọ́ Samuẹli. 4Dafidi àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli jáde lọ sí Jerusalẹmu (tí ṣe Jebusi). Àwọn Jebusi ara ilẹ̀ náà ń gbé níbẹ̀. 5Àwọn ará ìlú Jebusi sì wí fún Dafidi pé, “Ìwọ kò sì gbọdọ̀ wọ ìhín yìí wá.” Ṣùgbọ́n Dafidi kó ìlú odi Sioni—èyí tí í ṣe ìlú Dafidi.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.