Native Bible

1 Chronicles 11:24 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta.

1 Chronicles 11:24 in English

1 Chronicles 11:24 · Berean Standard Bible

These were the exploits of Benaiah son of Jehoiada, who won a name alongside the three mighty men.

Context

22Benaiah ọmọ Jehoiada ó sì jẹ́ akọni oníjà láti Kabṣeeli, ẹni tí ó ṣe iṣẹ́ agbára ńlá. Ó sì pa àwọn ọmọ Arieli méjì ti Moabu, ó sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí inú ihò lákokò yìnyín dídì, ó sì pa kìnnìún kan 23Ó sì pa ara Ejibiti ẹni tí ó ga ní ìwọ̀n ẹsẹ̀ méje àti ààbọ̀ ṣùgbọ́n àwọn ará Ejibiti wọn ní ọ̀kọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìdábùú igi ahunṣọ àti ọ̀pá ní ọwọ́ rẹ̀, Benaiah sọ̀kalẹ̀ lórí rẹ̀ pẹ̀lú kùmọ̀. Ó sì gba ọ̀kọ̀ náà láti ọwọ́ ará Ejibiti ó sì pa á pẹ̀lú ọ̀kọ̀ rẹ̀. 24Nǹkan wọ̀nyí sì ní ìwà akin Benaiah ọmọ Jehoiada; ohun náà pẹ̀lú sì di olókìkí gẹ́gẹ́ bí àwọn akọni ọkùnrin mẹ́ta. 25Ó sì ní ọlá púpọ̀ ju àwọn ọgbọ̀n lọ, ṣùgbọ́n a kò kà á láàrín àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Dafidi sì fi sí ìkáwọ́ àwọn ẹ̀ṣọ́. 26Àwọn akọni ọkùnrin náà nìyí: Asaheli arákùnrin Joabu, Elhanani ọmọ Dodo láti Bẹtilẹhẹmu,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.