1 Kronika 10:8
1 Chronicles 10:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa.
1 Chronicles 10:8 in English
1 Chronicles 10:8 · Berean Standard Bible
The next day, when the Philistines came to strip the dead, they found Saul and his sons fallen on Mount Gilboa.
Context
6Bẹ́ẹ̀ ni Saulu àti ọmọ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta kú, gbogbo ilé rẹ̀ sì kú ṣọ̀kan, lọ́jọ́ kan náà. 7Nígbà tí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli tí ó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ rí wí pé àwọn ọmọ-ogun ti sálọ àti pé Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ ti kú wọ́n kọ àwọn ìlú wọn sílẹ̀, wọ́n sì sálọ. Àwọn ará Filistini wá, wọ́n sì jókòó nínú wọn. 8Ní ọjọ́ kejì, nígbà tí àwọn ará Filistini wá láti kó òkú, wọ́n rí Saulu àti àwọn ọmọ rẹ̀ tí wọ́n ṣubú sórí òkè Gilboa. 9Wọ́n bọ́ ní aṣọ, wọ́n sì gbé orí rẹ̀ àti ìhámọ́ra rẹ̀, wọ́n sì rán ìránṣẹ́ lọ káàkiri ilẹ̀ àwọn ará Filistini láti kéde ìròyìn náà láàrín àwọn òrìṣà wọn àti àwọn ènìyàn wọn. 10Wọ́n gbé ìhámọ́ra rẹ̀ sí inú ilé tí wọ́n kọ́ fún òrìṣà wọn, wọ́n sì fi orí rẹ̀ kọ́ sí inú ilé Dagoni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.