Native Bible

Zechariah 6:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà.

Zechariah 6:11 in English

Zechariah 6:11 · Berean Standard Bible

Take silver and gold, make an ornate crown, and set it on the head of the high priest, Joshua son of Jehozadak.*

Context

9Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 10“Mú nínú ìgbèkùn, nínú àwọn Heldai, tí Tobiah, àti ti Jedaiah, tí ó ti Babeli dé, kí ìwọ sì wá ní ọjọ́ kan náà, kí o sì wọ ilé Josiah ọmọ Sefaniah lọ. 11Kí o sì mú fàdákà àti wúrà, kí o sì fi ṣe adé púpọ̀, sì gbé wọn ka orí Joṣua ọmọ Josadaki, olórí àlùfáà. 12Sì sọ fún un pé, ‘Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun sọ wí pé, wo ọkùnrin náà ti orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ẹ̀ka; yóò sì yọ ẹ̀ka láti abẹ́ rẹ̀ wá, yóò si kọ́ tẹmpili Olúwa wa. 13Òun ni yóò sì kọ́ tẹmpili Olúwa òun ni yóò sì wọ̀ ní ògo, yóò sì jókòó, yóò sì jẹ ọba lórí ìtẹ́ rẹ̀; òun ó sì jẹ́ àlùfáà lórí ìtẹ́ rẹ̀; ìmọ̀ àlàáfíà yóò sì wá láàrín àwọn méjèèjì.’

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.