Native Bible

Zechariah 5:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.”

Zechariah 5:2 in English

Zechariah 5:2 · Berean Standard Bible

“What do you see?” asked the angel. “I see a flying scroll,” I replied, “twenty cubits long and ten cubits wide.*”

Context

1Nígbà náà ni mo yípadà, mo sì gbé ojú mi sókè, mo sì wò, sì kíyèsi i, ìwé kíká ti ń fò. 2Ó sì wí fún mi pé, “Kí ni ìwọ rí?” Èmi sì dáhùn pé, “Mo rí ìwé kíká tí ń fò; gígùn rẹ̀ jẹ́ ogún ìgbọ̀nwọ́, ìbú rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́wàá.” 3Ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ègún tí ó jáde lọ sí gbogbo ilẹ̀ ayé, nítorí gbogbo àwọn tí ó bá jalè ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀; gbogbo àwọn tí ó bá sì búra èké ni a ó ké kúrò láti ìhín lọ nípa rẹ̀. 4Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Èmi yóò mú un jáde, Èmi yóò si wọ inú ilé olè lọ, àti inú ilé ẹni ti o bá fi orúkọ mi búra èké, yóò si wà ni àárín ilé rẹ̀, yóò si rún pẹ̀lú igi àti òkúta inú rẹ̀.’ ”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.