Native Bible

Zechariah 4:7 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ”

Zechariah 4:7 in English

Zechariah 4:7 · Berean Standard Bible

What are you, O great mountain? Before Zerubbabel you will become a plain. Then he will bring forth the capstone accompanied by shouts of ‘Grace, grace to it!’”

Context

5Angẹli tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Ìwọ kò mọ ohun tí àwọn wọ̀nyí jásí?” Mo sì wí pé, “Èmi kò mọ̀ ọ́n, olúwa mi.” 6Ó sì dáhùn ó sì wí fún mi pé, “Èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa sí Serubbabeli tó wí pé: ‘Kì í ṣe nípa ipá, kì í ṣe nípa agbára, bí kò ṣe nípa Ẹ̀mí mi,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 7“Ta ni ìwọ, ìwọ òkè ńlá? Ìwọ yóò di pẹ̀tẹ́lẹ̀ níwájú Serubbabeli: òun yóò sì fi ariwo mú òkúta téńté orí rẹ̀ wá, yóò máa kígbe wí pé, ‘Ọlọ́run bùkún fun! Ọlọ́run bùkún fun!’ ” 8Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ̀ mí wá, wí pé: 9“Ọwọ́ Serubbabeli ni a ti ṣe ìpìlẹ̀ ilé yìí, ọwọ́ rẹ̀ ni yóò sì parí rẹ̀; ìwọ yóò sì mọ̀ pé, Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni ó rán mi sí i yín.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.