Native Bible

Zechariah 14:13 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀.

Zechariah 14:13 in English

Zechariah 14:13 · Berean Standard Bible

On that day a great panic from the LORD will come upon them, so that each will seize the hand of another, and the hand of one will rise against the other.

Context

11Ènìyàn yóò sì máa gbé ibẹ̀, kì yóò sì sí ìparun mọ́; ṣùgbọ́n a ó máa gbé Jerusalẹmu láìléwu. 12Èyí ni yóò sì jẹ́ ààrùn tí Olúwa yóò fi kọlu gbogbo àwọn ènìyàn ti ó tí ba Jerusalẹmu jà; ẹran-ara wọn yóò rù nígbà tí wọn dúró ni ẹsẹ̀ wọn, ojú wọn yóò sì rà ni ihò wọn, ahọ́n wọn yóò sì bàjẹ́ ni ẹnu wọn. 13Yóò sì ṣe ni ọjọ́ náà, ìrọ́kẹ̀kẹ̀ ńlá láti ọ̀dọ̀ Olúwa wá yóò wà láàrín wọn; wọn ó sì di ọwọ́ ara wọn mú, ọwọ́ èkínní yóò sì dìde sì ọwọ́ èkejì rẹ̀. 14Juda pẹ̀lú yóò sì jà ni Jerusalẹmu: ọrọ̀ gbogbo àwọn kèfèrí tí ó wà káàkiri ni a ó sì kójọ, wúrà àti fàdákà, àti aṣọ, ní ọ̀pọ̀lọpọ̀. 15Bẹ́ẹ̀ ni ààrùn ẹṣin, ìbáaka, ìbákasẹ, àti tí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, yóò sì wà, àti gbogbo ẹranko tí ń bẹ nínú àgọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.