Native Bible

Zechariah 12:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè.

Zechariah 12:4 in English

Zechariah 12:4 · Berean Standard Bible

On that day, declares the LORD, I will strike every horse with panic, and every rider with madness. I will keep a watchful eye on the house of Judah, but I will strike with blindness all the horses of the nations.

Context

2“Kíyèsi í, èmi yóò sọ Jerusalẹmu dí àgọ́ ìwárìrì sí gbogbo ènìyàn yíká, nígbà tí wọn yóò dó ti Juda àti Jerusalẹmu. 3Ní ọjọ́ náà, nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá parapọ̀ sí i, ni èmi yóò sọ Jerusalẹmu di òkúta ti ko ṣe yí kúrò fún gbogbo ènìyàn, gbogbo àwọn tí ó bá sì fẹ́ yí i ni a ó gé sí wẹ́wẹ́, 4ní ọjọ́ náà,” ni Olúwa wí, “Ni èmi yóò fi ìdágìrì lu gbogbo ẹṣin, àti fi òmùgọ̀ kọlu ẹni tí ń gun un; èmi yóò sì ṣí ojú mi sí ilé Juda, èmi yóò sì bu ìfọ́jú lu gbogbo ẹṣin tí orílẹ̀-èdè. 5Àti àwọn baálẹ̀ Juda yóò sì wí ni ọkàn wọn pé, ‘Àwọn ara Jerusalẹmu ni agbára mi nípa Olúwa àwọn ọmọ-ogun ni Ọlọ́run wọn.’ 6“Ní ọjọ́ náà, ni èmi yóò ṣe àwọn baálẹ̀ Juda bí ààrò iná kan láàrín igi, àti bi ẹ̀fúùfù iná láàrín ìtí; wọn yóò sì jẹ gbogbo àwọn ènìyàn run yíká lápá ọ̀tún àti lápá òsì, a ó sì tún máa gbé inú Jerusalẹmu ní ipò rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.