Sekariah 11:9
Zechariah 11:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.”
Zechariah 11:9 in English
Zechariah 11:9 · Berean Standard Bible
Then I said, “I will no longer shepherd you. Let the dying die, and the perishing perish; and let those who remain devour one another’s flesh.”
Context
7Èmi yóò sì bọ́ ẹran àbọ́pa, àní ẹ̀yin òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran. Mo sì mu ọ̀pá méjì sọ́dọ̀; mo pè ọ̀kan ni Oore-ọ̀fẹ́, mo pè èkejì ni Àmùrè; mo sì bọ́ ọ̀wọ́ ẹran náà. 8Olùṣọ́-àgùntàn mẹ́ta ni mo sì gé kúrò ní oṣù kan.
Ọkàn mi sì kórìíra wọn, ọkàn wọn pẹ̀lú sì kórìíra mi. 9Mo sì wí pé, “Èmi kì yóò bọ́ yin: èyí ti ń ku lọ, jẹ́ kí òkú o kú; èyí tí a o ba sì gé kúrò, jẹ́ kí a gé e kúrò; ki olúkúlùkù nínú àwọn ìyókù jẹ́ ẹran-ara ẹnìkejì rẹ̀.” 10Mo sì mu ọ̀pá mi, ti a ń pè ní Oore-ọ̀fẹ́, mo ṣẹ́ si méjì, ki èmi bá lè da májẹ̀mú mi tí mo tí bá gbogbo àwọn ènìyàn náà dá. 11Ó sì dá ni ọjọ́ náà, bẹ́ẹ̀ ni àwọn òtòṣì nínú ọ̀wọ́ ẹran náà tí ó dúró tì mí mọ̀ pé, ọ̀rọ̀ Olúwa ni.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.