Sekariah 10:1
Zechariah 10:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa; Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná, tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn, fún olúkúlùkù koríko ní pápá.
Zechariah 10:1 in English
Zechariah 10:1 · Berean Standard Bible
Ask the LORD for rain in springtime; the LORD makes the storm clouds, and He will give everyone showers of rain and crops in the field.
Context
1Ẹ béèrè òjò nígbà àrọ̀kúrò ni ọwọ́ Olúwa;
Olúwa tí o dá mọ̀nàmọ́ná,
tí ó sì fi ọ̀pọ̀ òjò fún ènìyàn,
fún olúkúlùkù koríko ní pápá. 2Nítorí àwọn òrìṣà tí sọ̀rọ̀ asán,
àwọn aláfọ̀ṣẹ sì tí rí èké,
wọn sì tí rọ àlá èké;
wọ́n ń tu ni nínú lásán,
nítorí náà àwọn ènìyàn náà ṣáko lọ bí àgùntàn,
a ṣẹ wọn níṣẹ̀ẹ́, nítorí Olùṣọ́-àgùntàn kò sí. 3“Ìbínú mi ru sí àwọn darandaran,
èmi o sì jẹ àwọn olórí ní yà
nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun ti bẹ agbo rẹ̀,
ilé Juda wò,
yóò sì fi wọn ṣe ẹṣin rẹ̀ dáradára ní ogun.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.