Sekariah 1:2
Zechariah 1:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
“Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín.
Zechariah 1:2 in English
Zechariah 1:2 · Berean Standard Bible
“The LORD was very angry with your fathers.
Context
1Ní oṣù kẹjọ ọdún kejì ọba Dariusi, ọ̀rọ̀ Olúwa tọ wòlíì Sekariah ọmọ Berekiah, ọmọ Iddo pé: 2“Olúwa ti bínú sí àwọn baba ńlá yín. 3Nítorí náà sọ fún àwọn ènìyàn. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí: ‘Ẹ padà sí ọ̀dọ̀ mi,’ báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘èmi náà yóò sì padà sí ọ̀dọ̀ yín,’ ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí. 4Ẹ má dàbí àwọn baba yín, àwọn tí àwọn wòlíì ìṣáájú ti ké sí wí pé, báyìí ní Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín,’ àti kúrò nínú ìwà búburú yín; ṣùgbọ́n wọn kò gbọ́, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò fetí sí ti èmi, ni Olúwa wí.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.