Native Bible

Titus 1:9 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò.

Titus 1:9 in English

Titus 1:9 · Berean Standard Bible

He must hold firmly to the faithful word as it was taught, so that he can encourage others by sound teaching and refute those who contradict it.

Context

7Alábojútó jẹ́ ẹni tí a gbé iṣẹ́ Ọlọ́run lé lọ́wọ́, nítorí náà, kò gbọdọ̀ ní àbùkù kankan tàbí agbéraga, oníjà, kò gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀mùtí tàbí alágídí tàbí olójúkòkòrò. 8Wọ́n ní láti jẹ́ olùfẹ́ àlejò ṣíṣe, olùfẹ́ ohun tí ó dára. Wọ́n ní láti jẹ́ ẹni tí ó kò ara rẹ̀ ní ìjánu, ẹni dúró ṣinṣin, ọlọ́kàn mímọ́, àti ẹni oníwàtítọ́. 9Ó gbọdọ̀ di ẹ̀kọ́ nípa ìdúró ṣinṣin mú dáradára gẹ́gẹ́ bí ó ti kọ́ ọ, kí ó lè fi ẹ̀kọ́ tí ó yè kooro kọ́ àwọn ẹlòmíràn. Nípa èyí, yóò lè fi ìdí òtítọ́ múlẹ̀ fún àwọn alátakò. 10Nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn ni ọlọ̀tẹ̀, asọ̀rọ̀ asán àti ẹlẹ́tàn pàápàá jùlọ láàrín àwọn onílà. 11Ó gbọdọ̀ pa wọ́n lẹ́nu mọ́, nítorí wí pé wọ́n ń pa agbo Ọlọ́run run, nípasẹ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí kò jẹ́ èyí tí wọ́n ń kọ́ni. Èyí ni wọ́n ń ṣe fún ère àìṣòdodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.