Orin Solomoni 7:12
Song of Songs 7:12 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù láti wo bí àjàrà rúwé bí ìtànná àjàrà bá là. Àti bí pomegiranate bá ti rudi, níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ.
Song of Songs 7:12 in English
Song of Songs 7:12 · Berean Standard Bible
Let us go early to the vineyards to see if the vine has budded, if the blossom has opened, if the pomegranates are in bloom— there I will give you my love.
Context
10(9) Tí ó kúnná tí ó sì dùn,
tí ń mú kí ètè àwọn tí ó sùn kí ó sọ̀rọ̀.
(10) Ti olùfẹ́ mi ni èmi í ṣe,
èmi sì ni ẹni tí ó wù ú. 11Wá, olùfẹ́ mi, jẹ́ kí a lọ sí ibi pápá,
jẹ́ kí a lo àṣálẹ́ ní àwọn ìletò. 12Jẹ́ kí a lọ sínú ọgbà àjàrà ní kùtùkùtù
láti wo bí àjàrà rúwé
bí ìtànná àjàrà bá là.
Àti bí pomegiranate bá ti rudi,
níbẹ̀ ni èmi yóò ti fi ìfẹ́ mi fún ọ. 13Àwọn èso mándrákì mú òórùn wọn jáde
ní ẹnu-ọ̀nà wa ni onírúurú àṣàyàn èso,
èso tuntun àti ọjọ́ pípẹ́
tí mo ti kó pamọ́ fún ọ, olùfẹ́ mi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.