Native Bible

Ruth 3:8 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀.

Ruth 3:8 in English

Ruth 3:8 · Berean Standard Bible

At midnight, Boaz was startled, turned over, and there lying at his feet was a woman!

Context

6Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe. 7Nígbà tí Boasi parí jíjẹ àti mímu tán, tí ọkàn rẹ̀ sì kún fún ayọ̀. Ó lọ, ó sì dùbúlẹ̀ ní ẹ̀yìn ọkà tí wọ́n kójọ. Rutu yọ́ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ lọ sí ibẹ̀, ó ṣí aṣọ ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè, ó sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. 8Ó sì ṣe nígbà tí ọkùnrin náà tají ní àárín òru, ẹ̀rù bà á, ó sì yí ara padà, ó sì ṣàkíyèsí obìnrin kan tí ó sùn sí ibi ẹsẹ̀ rẹ̀. 9Ó sì béèrè pé, “Ta ni ìwọ í ṣe?” Rutu sì fèsì wí pé, “Èmi ni Rutu, ìránṣẹ́bìnrin rẹ. Da etí aṣọ rẹ bò mí, nítorí pé ìwọ ni ìbátan tí ó le è rà mí padà.” 10Boasi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa bùkún fún ọ, ọmọbìnrin mi. Ìfẹ́ tí o fihàn yí ti pọ̀ ju ti àtẹ̀yìnwá lọ, bí ó ti jẹ́ wí pé ìwọ kò lọ láti wá àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin bóyá ọlọ́rọ̀ tàbí tálákà.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.