Native Bible

Ruth 3:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.”

Ruth 3:4 in English

Ruth 3:4 · Berean Standard Bible

When he lies down, note the place where he lies. Then go in and uncover his feet, and lie down, and he will explain to you what you should do.”

Context

2Wò ó, Boasi ọkùnrin nì tí ìwọ bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́, tí í ṣe ìbátan wa, yóò wá láti fẹ́ ọkà barle ní ilẹ̀ ìpakà rẹ̀ ní àṣálẹ́ yìí. 3Wẹ̀, kí o sì fi ìpara olóòórùn dídùn pa ara rẹ, kí o sì wọ aṣọ rẹ tí ó dára jùlọ, kí o sì lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó gbé ń pa ọkà, ṣùgbọ́n má ṣe jẹ́ kí ó mọ̀ pé o wà níbẹ̀ títí tí yóò fi jẹ tí yóò sì mu tán. 4Rí í dájú pé o mọ ibi tí ó sùn sí, lẹ́yìn ìgbà tí ó bá ti sùn, lọ kí o ṣí aṣọ ìbora rẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀ sókè kí o sì sùn sí ibi ẹsẹ̀ náà. Òun yóò sì sọ ohun tí ìwọ yóò ṣe fún ọ.” 5Rutu sì fèsì pé, “Gbogbo ohun tí ìwọ sọ fún mi ni èmi yóò ṣe.” 6Bẹ́ẹ̀ ni Rutu lọ sí ilẹ̀ ìpakà tí ó sì ṣe gbogbo ohun tí ìyá ọkọ rẹ̀ sọ fún un, pé kí o ṣe.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.