Rutu 2:22
Ruth 2:22 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.”
Ruth 2:22 in English
Ruth 2:22 · Berean Standard Bible
And Naomi said to her daughter-in-law Ruth, “My daughter, it is good for you to work with his young women, so that nothing will happen to you in another field.”
Context
20Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.” 21Rutu, ará Moabu sì wí pé, “Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó sọ fún mi pé, ‘Kí ń máa ṣá ọkà pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ òun, títí wọn yóò fi parí ìkórè.’ ” 22Naomi sì sọ fún Rutu, ìyàwó ọmọ rẹ̀ pé, “Ìbá dára bí ó bá le bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin rẹ̀ ṣiṣẹ́. Nítorí pé wọ́n le è dà ọ́ láàmú bí o bá lọ sí oko ẹlòmíràn.” 23Rutu sì bá àwọn ìránṣẹ́bìnrin Boasi ṣiṣẹ́ títí tí wọ́n fi parí ìkórè ọkà barle àti ti jéró. Ó sì ń gbé pẹ̀lú ìyá ọkọ rẹ̀.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.