Native Bible

Ruth 2:18 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ó sì gbé e, ó sì lọ sí ìlú, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí ṣà bi o tí pọ̀ tó, Rutu sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀.

Ruth 2:18 in English

Ruth 2:18 · Berean Standard Bible

She picked up the grain and went into the town, where her mother-in-law saw what she had gleaned. And she brought out what she had saved from her meal and gave it to Naomi.

Context

16Bí kò ṣe pé kí ẹ mú lára àwọn ìtí sílẹ̀ fún láti ṣá, kí ẹ má sì ṣe ba a wí.” 17Rutu sì ń ṣá ọkà títí ó fi di ìrọ̀lẹ́, nígbà tí ó sì pa ọkà barle tí ó rí ṣà, tí ó sì fẹ́ ẹ tán, èyí tí ó rí sì tó ìwọ̀n garawa kan (lita méjìlélógún). 18Ó sì gbé e, ó sì lọ sí ìlú, ìyá ọkọ rẹ sì rí ọkà tí ó rí ṣà bi o tí pọ̀ tó, Rutu sì mú oúnjẹ tí ó jẹ kù lẹ́yìn tí ó ti yó tan fún ìyá ọkọ rẹ̀. 19Ìyá ọkọ rẹ̀ sì bi í léèrè wí pé, “Níbo ni ìwọ ti ṣá ọkà lónìí? Àti wí pé oko ta ni ìwọ gbé ṣiṣẹ́? Alábùkún fún ni ọkùnrin náà tí ó bojú wò ọ.” Rutu sì sọ ọ̀dọ̀ ẹni tí ó ti ṣiṣẹ́ fún ìyá ọkọ rẹ̀ pé, “Ní oko ọkùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Boasi ni mo ti ṣiṣẹ́ lónìí.” 20Naomi sì wí fún un pé, “Kí Olúwa, kí ó bùkún fún ọkùnrin náà. Ọlọ́run kò dáwọ́ oore àti àánú ṣíṣe sí àwọn alààyè àti òkú dúró.” Naomi sì sọ síwájú sí i wí pé, “Ìbátan tí ó súnmọ́ wa pẹ́kípẹ́kí ni ọkùnrin náà ń ṣe, ó sì jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn tí ó ní ẹ̀tọ́ láti ra ohun ìní ìdílé padà.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.