Native Bible

Romans 8:31 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa?

Romans 8:31 in English

Romans 8:31 · Berean Standard Bible

What then shall we say in response to these things? If God is for us, who can be against us?

Context

29Nítorí àwọn ẹni tí ó mọ̀ tẹ́lẹ̀, ni ó sì yàn tẹ́lẹ̀ láti rí bí àwòrán ọmọ rẹ̀, kí òun lè jẹ́ àkọ́bí láàrín àwọn arákùnrin púpọ̀. 30Àti pé lẹ́yìn tí òun ti pè wá wá sọ́dọ̀ ara rẹ̀, ó sọ wá di aláìjẹ̀bi lẹ́yìn èyí, ó fi rere Kristi kún inú ọkàn wa. Lékè gbogbo rẹ̀, ó fún wa ní ìdúró rere pẹ̀lú rẹ̀, ó sì pinu ògo rẹ̀ fún wa. 31Kí ni àwa yóò wí nísinsin yìí sí nǹkan ìyanu wọ̀nyí? Bí Ọlọ́run bá wà pẹ̀lú wa, ta ni yóò kọjú ìjà sí wa? 32Níwọ̀n ìgbà tí Ọlọ́run ti fi Ọmọ rẹ̀ fún wa, ǹjẹ́ ó ha tún le ṣòro fún un láti fún wa ní ohunkóhun bí? 33Ta ni ẹni náà tí ó lè dá wa lẹ́bi, àwa ẹni tí Ọlọ́run ti yàn fún ara rẹ̀. Ǹjẹ́ Ọlọ́run yóò dá wa lẹ́bi? Bẹ́ẹ̀ kọ́! Òun ni ẹni tí ó dáríjì wá, tí ó sì fi wá sípò tí ó dára lọ́dọ̀ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.