Native Bible

Romans 6:5 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde.

Romans 6:5 in English

Romans 6:5 · Berean Standard Bible

For if we have been united with Him like this in His death, we will certainly also be united with Him in His resurrection.

Context

3Tàbí ẹyin kò mọ pé gbogbo wa ti a ti bamitiisi wa sínú Jesu Kristi ni a ti bamitiisi sínú ikú rẹ. 4Nítorí náà, a sin wa pẹ̀lú Kristi nípa ìtẹ̀bọmi si ikú, kí ó bá le jẹ́ pe bí a ti jí Kristi dìde pẹ̀lú ògo Baba, àwa pẹ̀lú gbé ìgbé ayé tuntun. 5Nítorí pé ẹ̀yin ti di ọ̀kan ṣoṣo pẹ̀lú rẹ̀, àti pé ẹ kú pẹ̀lú rẹ̀, nígbà tí òun kú. Nísinsin yìí, ẹ ń pín ìyè tuntun rẹ̀, ẹ̀yin yóò sì jí dìde gẹ́gẹ́ bí òun náà ti jí dìde. 6Gbogbo èrò búburú ọkàn yín ni a kàn mọ́ àgbélébùú pẹ̀lú rẹ̀. Ẹ̀mí ẹ̀ṣẹ̀ tí ó sì ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ nínú yín ni a ti sọ di aláìlera. Nítorí náà, ara yín tí ó ń fẹ́ láti máa dẹ́ṣẹ̀ kò sí lábẹ́ àkóso ẹ̀ṣẹ̀ mọ́, kò sì ní láti jẹ́ ẹrú fún ẹ̀ṣẹ̀ mọ́. 7Nítorí pé nígbà tí ẹ ti di òkú fún ẹ̀ṣẹ̀, a ti gbà yín sílẹ̀ kúrò lọ́wọ́ gbogbo agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀ṣẹ̀ kò ní agbára lórí yín mọ́.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.