Native Bible

Romans 6:16 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀.

Romans 6:16 in English

Romans 6:16 · Berean Standard Bible

Do you not know that when you offer yourselves as obedient slaves, you are slaves to the one you obey, whether you are slaves to sin leading to death, or to obedience leading to righteousness?

Context

14Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ kì yóò tún ní ipá lórí yín mọ́, nítorí ẹ̀yin kò sí lábẹ́ ìdè òfin, bí kò ṣe lábẹ́ oore-ọ̀fẹ́. 15Ǹjẹ́ èyí túmọ̀ sí pé, nísinsin yìí, a lè tẹ̀síwájú láti máa dẹ́ṣẹ̀ láìbìkítà, nítorí ìgbàlà wa kò dúró nípa òfin mọ́, bí kò ṣe nípa gbígba oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run! 16Àbí ẹ̀yin kò mọ̀ pé, ẹnikẹ́ni lè yan ọ̀gá tí ó bá fẹ́? Ẹ lè yan ẹ̀ṣẹ̀ ti o yọrí si ikú tàbí ìgbọ́ràn ti o yọrí sí ìdáláre. Ẹnikẹ́ni tí ẹ bá fi ara yín fún, òun náà ni yóò jẹ́ ọ̀gá yín, ẹ̀yin yóò sì jẹ́ ẹrú rẹ̀. 17Ṣùgbọ́n ọpẹ́ ni fún Ọlọ́run pé, bí ẹ̀yin ti jẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ rí, ẹ̀yin jẹ́ olùgbọ́ran láti ọkàn wá sí àpẹẹrẹ ẹ̀kọ́ èyí tí Ọlọ́run fi lé yín lọ́wọ́. 18Nísinsin yìí, ẹ ti dòmìnira kúrò lọ́wọ́ ọ̀gá yín àtijọ́, èyí tí í ṣe ẹ̀ṣẹ̀, ẹ sì ti di ẹrú ọ̀gá tuntun èyí ni òdodo.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.