Native Bible

Romans 5:14 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀.

Romans 5:14 in English

Romans 5:14 · Berean Standard Bible

Nevertheless, death reigned from Adam until Moses, even over those who did not sin in the way that Adam transgressed. He is a pattern of the One to come.

Context

12Nítorí gẹ́gẹ́ bí ẹ̀ṣẹ̀ ti tipa ọ̀dọ̀ ènìyàn kan wọ ayé, àti ikú nípa ẹ̀ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ikú sì kọjá sórí ènìyàn gbogbo, láti ọ̀dọ̀ ẹni tí gbogbo ènìyàn ti dẹ́ṣẹ̀. 13Nítorí kí òfin tó dé, ẹ̀ṣẹ̀ ti wà láyé; ṣùgbọ́n a kò ka ẹ̀ṣẹ̀ sí ni lọ́rùn nígbà tí òfin kò sí. 14Ṣùgbọ́n ikú jẹ ọba láti ìgbà Adamu wá títí fi di ìgbà ti Mose, àti lórí àwọn tí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kò dàbí irú ìrékọjá Adamu, ẹni tí í ṣe àpẹẹrẹ ẹni tí ń bọ̀. 15Ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ kò dàbí ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí nípa ẹ̀ṣẹ̀. Nítorí bí o bá jẹ pé ẹnìkan ẹni púpọ̀ kú, mélòó mélòó ni oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, àti ẹ̀bùn nínú oore-ọ̀fẹ́ ọkùnrin kan, Jesu Kristi, di púpọ̀ fún ẹni púpọ̀. 16Kì í ṣe nípa ẹnìkan tí ó sẹ̀ ni ẹ̀bùn náà, nítorí ìdájọ́ ti ipasẹ̀ ẹnìkan wá fún ìdálẹ́bi, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn ọ̀fẹ́ ti inú ẹ̀ṣẹ̀ púpọ̀ wá fún ìdáláre.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.