Romu 4:11
Romans 4:11 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ó sì gbé àmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú.
Romans 4:11 in English
Romans 4:11 · Berean Standard Bible
And he received the sign of circumcision as a seal of the righteousness that he had by faith while he was still uncircumcised. So then, he is the father of all who believe but are not circumcised, in order that righteousness might be credited to them.
Context
9Ìbùkún yìí ha jẹ́ ti àwọn akọlà nìkan, tàbí ti àwọn aláìkọlà pẹ̀lú? Nítorí tí a wí pé, Abrahamu gba Ọlọ́run gbọ́, a sì kà á sí òdodo fún un. 10Báwo ni a ṣe kà á sí i? Nígbà tí ó wà ní ìkọlà tàbí ní àìkọlà? Kì í ṣe ni ìkọlà, ṣùgbọ́n ní àìkọlà ni. 11Ó sì gbé àmì ìkọlà àti èdìdì òdodo ìgbàgbọ́ tí ó ní nígbà tí ó wà ní àìkọlà kí ó lè ṣe baba gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́, bí a kò tilẹ̀ kọ wọ́n ní ilà kí a lè ka òdodo sí wọn pẹ̀lú. 12Àti baba àwọn tí ìkọlà tí kì í ṣe pé a kàn kọlà fún nìkan, ṣùgbọ́n tiwọn ń tẹ̀lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ tí baba wa Abrahamu ní, kí a tó kọ ọ́ nílà. 13Ìlérí fún Abrahamu àti fún irú-ọmọ rẹ̀, ni pé, wọn ó jogún ayé, kì í ṣe nípa òfin bí kò ṣe nípa òdodo ti ìgbàgbọ́.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.