Native Bible

Romans 2:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà?

Romans 2:4 in English

Romans 2:4 · Berean Standard Bible

Or do you disregard the riches of His kindness, tolerance, and patience, not realizing that God’s kindness leads you to repentance?

Context

2Ṣùgbọ́n àwa mọ̀ pé ìdájọ́ Ọlọ́run jẹ́ òtítọ́ si gbogbo àwọn tí ó ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí. 3Nítorí bí ìwọ tí ń ṣe ènìyàn lásán bá ń ṣe ìdájọ́ àwọn tí ń ṣe irú ohun báwọ̀nyí, tí ìwọ tìkára rẹ ń ṣe bẹ́ẹ̀, ìwọ ro èyí pé ìwọ o yọ nínú ìdájọ́ Ọlọ́run bí? 4Tàbí ìwọ ń gàn ọrọ̀ oore àti ìpamọ́ra àti sùúrù rẹ̀? Ìwọ kò ha mọ̀ pé oore Ọlọ́run ni ó ń fà ọ́ lọ sì ìrònúpìwàdà? 5Ṣùgbọ́n gẹ́gẹ́ bí líle àti àìronúpìwàdà ọkàn rẹ̀, ìwọ ń to ìbínú jọ fún ara rẹ de ọjọ́ ìbínú àti ìfihàn ìdájọ́ òdodo Ọlọ́run. 6Ọlọ́run yóò san án fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.