Romu 2:17
Romans 2:17 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run,
Romans 2:17 in English
Romans 2:17 · Berean Standard Bible
Now you, if you call yourself a Jew; if you rely on the law and boast in God;
Context
15Àwọn ẹni tí ó fihàn pé, a kọ̀wé iṣẹ́ òfin sí wọn lọ́kàn, tí ẹ̀rí ọkàn wọn pẹ̀lú sì tún ń jẹ́ wọn lẹ́rìí, àti pé, èrò ọkàn wọn tí ó jẹ́ ọ̀nà ìfinisùn, sì ń gbè wọ́n lẹ́yìn ní ìsinsin yìí. 16Èyí yóò farahàn ní ọjọ́ náà nígbà tí Ọlọ́run yóò tipasẹ̀ Jesu Kristi ṣe ìdájọ́ àwọn àṣírí ènìyàn gẹ́gẹ́ bí ìyìnrere mi. 17Ṣùgbọ́n bí a bá ń pe ìwọ ní Júù, tí o sì sinmi lé òfin, tí o sì ń ṣògo nínú ìbálòpọ̀ rẹ̀ sí Ọlọ́run, 18tí o sì mọ ìfẹ́ rẹ̀, tí o sì fọwọ́sí ohun tí ó dára jùlọ, nítorí tí a ti kọ́ ọ ní òfin; 19tí o sì dá ara rẹ lójú pé ìwọ ni amọ̀nà àwọn afọ́jú, ìmọ́lẹ̀ fún àwọn tí ó wà ni òkùnkùn,
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.