Romu 16:26
Romans 16:26 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́;
Romans 16:26 in English
Romans 16:26 · Berean Standard Bible
but now revealed and made known through the writings of the prophets by the command of the eternal God, in order to lead all nations to the obedience that comes from faith *—
Context
23Gaiusi, ẹni tí èmi àti gbogbo ìjọ gbádùn ìtọ́jú wa tí ó ṣe náà fi ìkíni ránṣẹ́.
Erastu, ẹni tí ó jẹ́ olùtọ́jú ìṣúra ìlú, àti arákùnrin wa Kuartu fi ìkíni wọn ránṣẹ́.* 25Ǹjẹ́ fún ẹni tí ó ní agbára láti fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ nípa ìyìnrere mi àti ìpolongo Jesu Kristi, gẹ́gẹ́ bí ìṣípayá ohun ìjìnlẹ̀ tí a ti pamọ́ láti ìgbà ayérayé, 26ṣùgbọ́n, nísinsin yìí, a ti fihàn nípa ìwé mímọ́ àwọn wòlíì, àti gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Ọlọ́run ayérayé pa, kí gbogbo orílẹ̀-èdè le ní ìgbọ́ràn tí ó wá láti inú ìgbàgbọ́; 27kí ògo wà fún Ọlọ́run, ẹnìkan ṣoṣo tí ọgbọ́n í ṣe tirẹ̀ nípa Jesu Kristi títí láé! Àmín.
16.23 Àwọn àkọsílẹ̀ àtijọ́ kan se àfikún ọ̀rọ̀ yìí ìkíni wọn ránṣẹ́.24 Ǹjẹ́ kí oore-ọ̀fẹ́ Jesu Kristi Olúwa wa, kí ó wà pẹ̀lú gbogbo yín. Àmín.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.