Native Bible

Romans 16:2 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú.

Romans 16:2 in English

Romans 16:2 · Berean Standard Bible

Welcome her in the Lord in a manner worthy of the saints, and assist her with anything she may need from you. For she has been a great help to many people, including me.

Context

1Mo fi Febe arábìnrin wa le yin lọ́wọ́, ẹni tí ó jẹ́ díákónì nínú ìjọ tí ó wà ní Kenkerea. 2Mo rọ̀ yín kí ẹ gbà á ní orúkọ Olúwa, bí ó ti yẹ fún àwọn ènìyàn mímọ́, kí ẹ̀yin kí ó sì ràn án lọ́wọ́ ní gbogbo ọ̀nà, nítorí pé òun jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn àti fún èmi náà pẹ̀lú. 3Ẹ kí Priskilla àti Akuila, àwọn tí ó ti jẹ́ alábáṣiṣẹ́pọ̀ mi nínú Kristi Jesu. 4Àwọn tí wọ́n ti fi ẹ̀mí wọn wéwu nítorí mi. Kì í ṣe èmi nìkan àti gbogbo àwọn ìjọ àwọn aláìkọlà ń dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.