Romu 15:27
Romans 15:27 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017
Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ.
Romans 15:27 in English
Romans 15:27 · Berean Standard Bible
They were pleased to do it, and indeed they owe it to them. For if the Gentiles have shared in their spiritual blessings, they are obligated to minister to them with material blessings.
Context
25Ṣùgbọ́n ní báyìí, mo ń lọ sí Jerusalẹmu láti sé ìránṣẹ́ fún àwọn ènìyàn mímọ́ níbẹ̀. 26Nítorí pé ó wu àwọn tí ó wà ní Makedonia àti Akaia láti kó owó jọ fún àwọn tálákà tí ó wà ní àárín àwọn ènìyàn mímọ́ ní Jerusalẹmu. 27Pẹ̀lú ayọ̀ ni wọ́n ń ṣe èyí, nítorí wọ́n gbà wí pé, wọ́n jẹ́ ajigbèsè fún wọn. Nítorí bí ó bá ṣe pé a fi àwọn Kèfèrí ṣe alájọni nínú ohun ẹ̀mí wọn, ajigbèsè sì ni wọn láti fi ohun ti ara ta wọ́n lọ́rẹ. 28Nítorí náà, nígbà tí mo bá ti ṣe èyí tán, tí mo bá sì di èdìdì èso náà fún wọn tán, èmi yóò ti ọ̀dọ̀ yín lọ sí Spania. 29Mo sì mọ̀ pé nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, èmi yóò wà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìbùkún ìyìnrere Kristi.
Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.