Native Bible

Romans 14:4 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró.

Romans 14:4 in English

Romans 14:4 · Berean Standard Bible

Who are you to judge someone else’s servant? To his own master he stands or falls. And he will stand, for the Lord is able to make him stand.

Context

2Ẹnìkan gbàgbọ́ pé òun lè máa jẹ ohun gbogbo: ṣùgbọ́n ẹlòmíràn tí ó sì jẹ́ aláìlera ní ìgbàgbọ́ ń jẹ ewébẹ̀ nìkan. 3Kí ẹni tí ń jẹ ohun gbogbo má ṣe kẹ́gàn ẹni tí kò jẹ; kí ẹni tí kò sì jẹ ohun gbogbo kí ó má ṣe dá ẹni tí ń jẹ lẹ́bi nítorí Ọlọ́run ti gbà á. 4Ta ni ìwọ láti dá ọmọ ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Lójú olúwa tirẹ̀ ni òun dúró, tàbí ṣubú. Òun yóò sì dúró nítorí Ọlọ́run ní agbára láti mú kí òun dúró. 5Ẹnìkan bu ọlá fún ọjọ́ kan ju òmíràn; ẹlòmíràn bu ọlá fún ọjọ́ gbogbo bákan náà. Kí olúkúlùkù kí ó dá ara rẹ̀ lójú ní inú ara rẹ̀. 6Ẹni tí ó bá ya ọjọ́ kan sí ọ̀tọ̀, ó ń yà á sọ́tọ̀ fún Olúwa. Ẹni tí ó ń jẹ ẹran, ó ń jẹ ẹran fún Olúwa, nítorí pé òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run; ẹni tí kò bá sì jẹ ẹran, kò jẹ ẹran fún Olúwa, òun náà dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.