Native Bible

Romans 11:23 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀.

Romans 11:23 in English

Romans 11:23 · Berean Standard Bible

And if they do not persist in unbelief, they will be grafted in, for God is able to graft them in again.

Context

21Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí. 22Nítorí náà wo oore àti ìkáàánú Ọlọ́run; lórí àwọn tí ó ṣubú, ìkáàánú; ṣùgbọ́n lórí ìwọ, oore, bi ìwọ bá dúró nínú oore rẹ̀; kí a má bá ké ìwọ náà kúrò. 23Àti àwọn pẹ̀lú, bí wọn kò bá jókòó sínú àìgbàgbọ́, a ó lọ́ wọn sínú rẹ̀, nítorí Ọlọ́run le tún wọn lọ́ sínú rẹ̀. 24Nítorí bí a bá ti ké ìwọ kúrò lára igi òróró igbó nípa ẹ̀dá rẹ̀, tí a sì lọ́ ìwọ sínú igi òróró rere lòdì sí ti ẹ̀dá; mélòó mélòó ni a ó lọ́ àwọn wọ̀nyí, tí í ṣe ẹ̀ka-ìyẹ́ka sára igi òróró wọn? 25Ará, èmi kò ṣá fẹ́ kí ẹ̀yin kí ó wà ní òpè ní ti ohun ìjìnlẹ̀ yìí, kí ẹ̀yin má ba á ṣe ọlọ́gbọ́n ní ojú ara yín, pé ìfọ́jú bá Israẹli ní apá kan, títí kíkún àwọn Kèfèrí yóò fi dé.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.