Native Bible

Romans 11:19 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.”

Romans 11:19 in English

Romans 11:19 · Berean Standard Bible

You will say then, “Branches were broken off so that I could be grafted in.”

Context

17Ṣùgbọ́n bí a bá ya nínú àwọn ẹ̀ka kúrò, tí a sì lọ́ ìwọ, tí í ṣe igi òróró igbó sára wọn, tí ìwọ sì ń bá wọn pín nínú gbòǹgbò àti ọ̀rá igi olifi náà, 18má ṣe ṣe féfé sí àwọn ẹ̀ka igi náà. Ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ṣe féfé, ìwọ kọ́ ni ó rù gbòǹgbò, ṣùgbọ́n gbòǹgbò ni ó rù ìwọ. 19Ǹjẹ́ ìwọ ó wí pé, “A ti fa àwọn ẹ̀ka náà ya, nítorí kí a lè lọ́ mi sínú rẹ̀.” 20Ó dára; nítorí àìgbàgbọ́ ni a ṣe fà wọn ya kúrò, ìwọ sì dúró nípa ìgbàgbọ́ rẹ. Má ṣe gbé ara rẹ ga, ṣùgbọ́n bẹ̀rù. 21Nítorí bí Ọlọ́run kò bá dá ẹ̀ka-ìyẹ́ka sí, kíyèsára kí ó má ṣe ṣe àìdá ìwọ náà sí.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.