Native Bible

Romans 11:1 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Ǹjẹ́ mo ní, Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini.

Romans 11:1 in English

Romans 11:1 · Berean Standard Bible

I ask then, did God reject His people? Certainly not! I am an Israelite myself, a descendant of Abraham, from the tribe of Benjamin.

Context

1Ǹjẹ́ mo ní, Ọlọ́run ha ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù bí? Kí a má ri. Nítorí Israẹli ni èmi pẹ̀lú, láti inú irú-ọmọ Abrahamu, ni ẹ̀yà Benjamini. 2Ọlọ́run kò ta àwọn ènìyàn rẹ̀ nù ti ó ti mọ̀ tẹ́lẹ̀. Tàbí ẹ̀yin kò mọ bí ìwé mímọ́ ti wí ní ti Elijah? Bí ó ti ń bẹ̀bẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run fún Israẹli, wí pé: 3“Olúwa, wọ́n ti pa àwọn wòlíì rẹ, wọn sì ti wó àwọn pẹpẹ rẹ lulẹ̀; èmi nìkan ṣoṣo ni ó sì kù, wọ́n sì ń wá ẹ̀mí mi.”

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.