Native Bible

Romans 1:29 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́.

Romans 1:29 in English

Romans 1:29 · Berean Standard Bible

They have become filled with every kind of wickedness, evil, greed, and depravity. They are full of envy, murder, strife, deceit, and malice. They are gossips,

Context

27Gẹ́gẹ́ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọkùnrin pẹ̀lú, wọn a máa fi ìbálòpọ̀ obìnrin nípa ti ẹ̀dá sílẹ̀, wọn a máa fẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sí ara wọn, ọkùnrin ń bá ọkùnrin ṣe èyí tí kò yẹ, wọ́n sì ǹ jẹ èrè ìṣìnà wọn nínú ara wọn bí ó ti yẹ sí. 28Àti gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti kọ̀ láti gba Ọlọ́run nínú ìmọ̀ tí ó tọ́, Ọlọ́run fi wọ́n fún iyè ríra láti ṣe ohun tí kò tọ́ fún wọn láti ṣe. 29Wọ́n kún fún onírúurú àìṣòdodo gbogbo, àgbèrè, ìkà, ojúkòkòrò, àrankàn; wọ́n kún fún ìlara, ìpànìyàn, ìjà, ìtànjẹ, ìwà búburú; wọ́n jẹ́ afọ̀rọ̀kẹ́lẹ́ ba ni jẹ́. 30Asọ̀rọ̀ ẹni lẹ́yìn, akórìíra Ọlọ́run, aláfojúdi, agbéraga, ahalẹ̀, aláròṣe ohun búburú, aṣàìgbọràn sí òbí, 31aláìníyè nínú, ọ̀dàlẹ̀, aláìnígbàgbọ́, ọ̀dájú, aláìláàánú.

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.