Native Bible

Romans 1:20 · Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible 2017

Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí.

Romans 1:20 in English

Romans 1:20 · Berean Standard Bible

For since the creation of the world God’s invisible qualities, His eternal power and divine nature, have been clearly seen, being understood from His workmanship, so that men are without excuse.

Context

18Ṣùgbọ́n Ọlọ́run fi ìbínú rẹ̀ hàn láti ọ̀run wá sí gbogbo àìwà-bí-Ọlọ́run àti gbogbo àìṣòdodo ènìyàn, àwọn tí ń fi ìwà búburú dènà ìmọ̀ òtítọ́ lọ́dọ̀ ènìyàn. 19Nítorí pé, nǹkan gbogbo tí a lè mọ nípa Ọlọ́run ni a ti fihàn fún wọn, nítorí Ọlọ́run ti fi í hàn fún wọn. 20Nítorí pé láti ìgbà dídá ayé, gbogbo ohun àìlèfojúrí rẹ̀, bí agbára ayérayé àti ìwà-bí-Ọlọ́run rẹ̀ ni a rí gbangba tí a sì ń fi òye ohun tí a dá mọ̀ ọ́n kí ènìyàn má ba à wá àwáwí. 21Lóòótọ́, wọn ní òye nípa Ọlọ́run dáradára, ṣùgbọ́n wọn kò yìn ín lógo bí Ọlọ́run, wọ́n kò sí dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀; wọ́n ń ro èrò asán, ọkàn aṣiwèrè wọn sì ṣókùnkùn. 22Níwọ́n bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé wọ́n pe ara wọn ní ọlọ́gbọ́n ṣùgbọ́n wọ́n di òmùgọ̀ pátápátá,

Yorùbá text and audio: Biblica® Open Yorùbá Contemporary Bible™, made available under an open license by Biblica, Inc.